Òwe Yorùbá B

Òwe Yorùbá B

1. Bá inú sọ sọ má bá ènìyàn sọ torí èké ni ayé wọn kò ṣe fi inú hàn.
2. Bá mi na ọmọ mi kò de inú olómi.
3. Baba ọmọ ló ní ọmọ, àgbon ìsàlẹ̀ lo ni houhou.
4. Báwo ni ẹ ṣe ni yóò rí, ọmọ olè tí ń gún ìbaaka.
5. Báyìí ni a ń ṣe ní ilé wa, eewọ ibòmíràn ni.
6. Bí a bá bẹ igi ni igbó, a fi ọrọ ro ara ẹni wò.
7. Bí a bá dá aṣọ fún olè, a sì paa ni aró.
8. Bí a bá dá wéré dá òkú ìyá rè, ó ṣe ṣe kí ó fi í jẹ tán.
9. Bí a bá fi àgbò fún ègúnègún à á fi okùn rè sílè
10. Bí a bá kó aṣọ fún ọ̀bùn, ọ̀bùn yóò lo aṣọ gbó.
11. Bí a bá léni tí a kò bá báni, ìwọ̀n ni àá báni sọ̀tá mọ.
12. Bí a bá ń gbálẹ̀ sí ìta, àkìtàn ni a ń darí rẹ sì.
13. Bí a bá ń gunyan fún máfẹ́ kò ní fẹ́, bí a sì ń roka fún mọ́gbà kò ní gbà.
14. Bí a bá ń gunyan nínú kòtò ọwọ́, tí a sì ń sebẹ̀ nínú èpo ẹ̀pà, ẹni máa yo á yó.
15. Bí a bá ń kì àgbè ní àkíjù á rò pé wón fẹ́ tọrọ isu lọ́wọ́ òun ni.
16. Bí a bá ń sunkún, á máa n ríran.
17. Bí a bá ní kí a wo tí pẹ̀là lójú agbo, ìjọ á bàjé, bí a kò bá sì wo tí pẹ̀là ìjọ kò ní dùn.
18. Bí a bá pe orí ajá, a ó pè orí ìkòkò tí wón fi sẹ̀ é.
19. Bí a bá sọ òkò(òkúta) sì ọjà, ará ilé ẹni níí bá.
20. Bí a bá ta ará ilé ẹni lọ́pọ̀, a kò le rí i rà ní ọ̀wọ́n.
21. Bí a bá tá kí á tọ̀ ó, bí a kò bà tọ̀ ó, ẹran onídin níí dà.
22. Bí a bá ti ń lu ìlù kóǹkóto, kótokòto náà ni yóò maa dún.
23. Bí a kò bá kú, a ó jẹ ẹran tí ó tó erin.
24. Bí a kò kú ìṣe kò tán.
25. Bí a se rìn ní àá kò ní, sìn mí ká lọ sí òde lọ gbé ẹ̀wù ẹtù wọ̀.
26. Bí a ṣe fẹ́ rí, bí a ṣe fẹ́ tó, a kò rí bẹ nítorí pé bí a ṣe fẹ́ mọ lo dúró tì wá yìí.
27. Bí abẹ́rẹ́, bí abẹ́rẹ́ ni à ṣe èké, ijọ́ tí ó bá tó oko ro ní pani.
28. Bí àbíkú bá ń wáyé lọ́dọọdún, ọjọ́ orí rẹ̀ kò le tó ti bàbá rẹ̀.
30. Bí afínjú bá ní ọkọ tirè tán, ọ̀bùn náà á sì ní tirẹ̀.
31. Bí ajá kò bá rí kì í gbó.
32. Bí apá kò bá ṣé ṣán, ṣe ni à ka sí orí.
33. Bí aya bá mọ ojú ọkọ tán alárinà a yẹ̀bá.
34. Bí eégbon bá wà lẹ́nu àyìnrín, adìẹ kò ni yóò mu un kúrò.
35. Bí èkúté kò bá se àgbèrè kò gbọdọ sì adíkálà nínú ọmọ rẹ̀.
36. Bí erin bá jẹ ti kò yó, ìgbẹ́ ni ojú yóò tì.
37. Bí etí kò bá gbó yìnkìn, inú kì í bàjẹ́.
38. Bí ewé bá pé lára ọsẹ, á di ọsẹ.
39. Bí ewúré bá bojú wẹ̀hìn, a fi èpè fún elépè.
40. Bí ewúrẹ́ bá dá ní, àgbà ìjàkadì ni.
41. Bí ẹ̀bìtì kò bá pa eku mọ́, á fi ẹyìn fún ẹlẹ́yìn.
42. Bí ẹyẹ bá ṣe ń fò ni a sọ òkò rẹ̀.
43. Bí ó ti le wù kí irun ojú àgùntàn gùn tó, ayé ni ó bá irun ìpénpèéjú.
44. Bí o ti wù kí imú alágbàro gùn tó, ẹni tí ó gbé oko fún un ní ọ̀gá rè.
45. Bí màálù bá ń ṣe àìsàn fún ogún ọdún kò ní kí ẹran rẹ̀ má kún ìkòkò.
46. Bí ohun tí a ń jẹ bá tán, èyí tí a kìí jẹ ní a ń tá owó sí.
47. Bọ́ ọmọ ìyá méjì bá ń jà ara wọn lóògùn, ọmọ bàbà nii jogún wọn.
48. Bọ̀rọ̀kìnní àṣẹ jù oko olówó ní mú wọn lọ.
49. Bí pẹ́pẹ́yẹ bá jẹ òkúta, omi ni yóò fi su.
50. Bí sò ìyà yóò bá di egbò, olúkànbí làá sọ fún.

Share:

Share on facebook
Share on twitter
Share on email
Share on whatsapp
Share on telegram

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *