Òwe Yorùbá A

Òwe Yorùbá A

1. Ààbò òrò nii àá so fún omolúàbí, bí ó dé inú rè á di odidi.
2. Àbá ni ikán ń dá, ikán kò leè mu òkúta.
3. Àbámò ní gbèhìn òrò.
4. Abánigbé má mo ìwà eni, òtá eni níí se.
5. Àbíkú so olóògùn-dèké
6. Abínú eni kò lè pa kàdàrá dà.
7. Àbí-ìkóó, àkóó-gba, òde ni wón ti ń kó ogbón wá.
8. Abíyamo òtá àgàn, eni tí ó ń sisé ni òtá òle.
9. Àdabà ń fò ògèdè ó se bí ęyęle kò gbó, ęyęle gbó        títiiri ni ó ń tiiri.
10. Àdán dorí kodò ó ń wòse ęyę
11. A dá ké má fohùn a kò mọ tí ẹni tí ń ṣe.
12. Àdáni lóró fi agbára kọ́ni.
13. A dé ibi ẹyin má sì í àgbà ọ̀le.
14. Adé ni a fi mọ ọba, ìlékè ni a fi ń mọ ìjòyè.
15. Adìẹ ìbá ni o kó ìbá fi ojú àkìtàn rí nǹkan.
16. Adìẹ funfun kò mọ ara rẹ ní àgbà.
17. A fi idà pa ènìyàn kì í jẹ ki a mú idà kọjá lẹgbẹẹ ohun.
18. A fi asẹ́ gbe ọ̀jọ̀ ó tan ara rẹ̀ jẹ.
19. Àfọ̀piná tí ó ní òun yóò pá pa fìtílà ara rẹ̀ ni yóò pá.
20. A-fún-ní-jẹ ki í fún ni tá.
21. Àgàn tí ń gbé ọmọ ẹgbẹ́ rẹ jó, ojú ni o ń rọ.
22. Àgbà kò sì ní i ìgbẹ́ Ọ̀kẹ́rẹ́, ẹni tí yóò jẹ ẹran a dé igbó.
23. A kì í dákẹ́ kí a sì ìwà hù, a kì í wò sùn-ùn kí a dá rán.
24. A kì í là oyin kí á tu itọ́ rẹ̀ sílẹ̀.
25. A kì í mọ̀ ọ́n rín kí a tán ayé já.
26. A kì í ti ojú ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́sàn án ká á.
27. A kì í ti ojú ogun wa efọ́n.
28. A kì í rí ọmọ ọba kí á má rí “dàńsáákì” lára rẹ̀.
29. A kì í wí síbè kí á kú síbẹ̀.
30. A kì í wáyé kí á má ní àrùn kan lára.
31. A ní ká panupọ̀ bá olè wí, a ní ibi tí Ọlọhun fi ohun sí kò dára.
32. A kúkú ìjòyè ó sàn ju mo jẹ oyè ẹnu mi kò ká ìlú lọ.
33. Alásìwí ni àámú a kì í mú alásì dákẹ́.
34. Amúkùń ẹrú rẹ wọ́, ó ń òkè ní òkè ni ẹ ń wò, ẹ kò wo ilẹ̀.
35. Apẹ́ kí ó tó jẹun kì í jẹ ìbàjé.
36. Aráyé ni òkun, ènìyàn ni ọ̀sà, ẹni tí kò mọ̀ọ́wẹ̀ tí ó kán lu omi ayé, omi ayé yóò gbe lọ.
37. Àsọ̀rọ̀ a ìlà ni ó pa elémpè ìṣáájú, tí ó ní igbá wúwo ju awo lọ.
38. Asunrárà tí ó ń sun rárà fún ọmọ ẹgbẹ́ rè jó akọ iṣẹ́ ni ó ń ṣe.
38. Atiro tí ó rán Ọmọ ní bàtà ẹsẹ kan, ọ̀rọ̀ ni ó kú tí ó fé gbọ́.
39. Àtòrì ni ayé bí ó bá lò síwájú, á tún ló sí ẹ̀hìn.
40. A ti ẹ̀hìn kò ọgbọ́n, a gé etí ajá tán à ń fi ọ̀bẹ pamọ́.

Share:

Share on facebook
Share on twitter
Share on email
Share on whatsapp
Share on telegram

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *